Wo Ìbejì àádọ̀rún ọdún tó kọ́lé papọ̀ àti aáwọ̀ tó mú kí wọn pín ilé náà + VIDEO 🎊 The Scoper Media

 

 

Àkọlé fídíò,Obasa Twins: Àwọn aya wọn ní Tayé ló burú púpọ̀, ó máa ń sọ̀rọ̀ sí ìkejì rẹ̀ bíi ọmọdé ni
Wo Ìbejì àádọ̀rún ọdún tó kọ́lé papọ̀ àti aáwọ̀ tó mú kí wọn pín ilé náà

Ayọ nla ni o ma n jẹ fun obi lati bi ibaje tabi ibẹta nitori oore onilọpo meji ni wọn jẹ.

Amọ nigba miran irufẹ awọn ibeji tabi ibẹta bẹẹ kii pẹ ki ọkan to jade laye ninu wọn.

Sugbọn iyalẹnu nla lo maa n jẹ lati ri awọn ibeji ti wọn dagba pe ẹni aadọrun ọdun eyi ti ko wọpọ.

BBC Yoruba se alabapade awọn baba agba meji ti wọn jẹ ibeji, Taiwo ati Kehinde Obasa ni Abule Ẹgba nilu Eko.

A ba wọn sọrọ lori ajọsepọ wọn, ile ti wọn kọ papọ ati idi ti wọn se pin ile naa.

Bakan naa la tun ba awọn aya wọn sọrọ lori ajọsepọ ati ibagbepọ wọn.

Ibeji Obasa atawọn aya wọn

Bi ìbẹ̀rẹ̀ igbe aye wa se lọ ree – Ibeji Obasa

Nigba ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ, awọn ibeji Obasa salaye nipa igbe aye wọn.

Wọn ni ọjọ Keji, osu Keji ọdun 1934 ni awọn dele aye eyi to ti pe aadọrun ọdun sẹyin.

Agbegbe Itori Odo nilu Abeokuta si ni wọn ti bi wn.

Awọn mejeeji n gbe papọ, sisẹ papọ, ti akọkọ ninu wọn si fẹ iyawo ni ọdun 1965 nigba ti o si bi akọbi lọdun 1966.

Ọdun 1972 ni wọn pa owo pọ ra ilẹ kan soso pẹlu ẹgbẹrun kan Naira silu Abeokuta..

Ọdun 1979 si 1980 si ni wọn ko lọ sile naa pẹlu awọn aya wọn.

Awọn iyawo Ibeji Obasa

Ìkọ́lépọ̀ kò rọrùn, a máa ń jà amọ́ torí a jẹ́ onígbàgbọ́ ló ṣe rọrùn – Àwọn aya ìbejì Obasa

Nigba ti awọn naa n ba BBC Yoruba sọrọ awọn iyawo si awọn ibeji naa salaye pe lootọ ni awọn maa n ja ninu ile ti awọn dijọ n gbe.

Bakan naa ni awọn ọkọ wọn fidi rẹ mulẹ pe awọn iyawo awọn maa n tahun sira wọn ninu ile amọ awọn maa n pari rẹ fun wọn ni.

“Ikọlepọ ko rọrun rara, a maa n ja pupọ amọ a maa n pari rẹ laarin ara wa.

O tun rọtun lati gbe ile papọ nitori pe onigbagbọ lo tun se rọrun lati gbe ile papọ tabi pari ija laarin ara wa.”

Taiwo ati Kehinde Obasa

“Taye buru gan, se lo maa n sọrọ si ikeji rẹ̀ bii ọmọde”

Awọn ibeji Obasa yii tun salaye pe awọn ti pin ile ti awọn dijọ kọ.

Ọkan mu ila ile kan delẹ, ti ekeji si mu ila keji ile delẹ ninu ile ilẹ ti wọn dijọ kọ papọ.

Awọn mejeeji gba pe awọn maa n ja pupọ, amọ lati ọdun mẹẹdogun sẹyin ni awọn ko ti ja mọ tori awọn ti mọ iwa ara awọn daadaa.

Taye wa fọwọ sọya fun BBC Yoruba pe oun ni oun buru julọ laarin awọn mejeeji, ti ẹnikeji oun si tutu niwa.

Bakan naa ni awọn aya wọn fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni Taye buru pupọ.

“Taye buru gan, suuru wọn si ku diẹ kaa to.

Se lo maa n bu ikeji rẹ bii igba to n bu ọmọ kekere ni.

Amọ bi wọn se n ja to yii, ko si ẹni to joko pari ija fun wọn.”

 

FirstBank AD
Adron Advert
Access Bank advert

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *